Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 494: Dúró Pẹ̀lú Ọkàn Kan

Standing By A Purpose True

Dúró pẹ̀lú ọkàn kan,
Ṣe 'fẹ́ Ọlọ́run,
Yìn àwọn olótítọ́,
Àwọn ẹgbẹ́ Daniel'!

Ṣe gẹ́gẹ́ bí Daniel'
Má wò ẹnìkan!
Ní èrò rere l' ọkàn!
Sì jẹ́ kí ayé mọ̀.

Ọ̀pọ̀ akín l' ó ń ṣègbé,
Wọ́n kò tó dúró;
Wọ́n bá wọ ẹgbẹ́ Daniel',
Wọ́n bá jà f' Ọlọ́run.

Ṣe gẹ́gẹ́ bí Daniel'
Má wò ẹnìkan!
Ní èrò rere l' ọkàn!
Sì jẹ́ kí ayé mọ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀mìíràn,
Tí ń halẹ̀ kiri
Ni ìbá ṣubú lù ilé
B' ẹgbẹ́ Daniel' kọ́ wọn!

Ṣe gẹ́gẹ́ bí Daniel'
Má wò ẹnìkan!
Ní èrò rere l' ọkàn!
Sì jẹ́ kí ayé mọ̀.

Gb' ọpágun 'hìn-rere ga!
Ẹ máa ṣẹ́gun ń sọ!
Pé ogun Èṣù ń 'jà,
Hó yẹẹ f' ẹgbẹ́ Daniel'!

Ṣe gẹ́gẹ́ bí Daniel'
Má wò ẹnìkan!
Ní èrò rere l' ọkàn!
Sì jẹ́ kí ayé mọ̀.