Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 49: Ẹ Wá K' Á Kọrin S' Olúwa
O Come Let Us Sing To The Lord
Ẹ wá k' á kọrin s' Olúwa,
K' ẹnìkọ̀ọ̀kan wa wá;
Kí a hó ihó ayọ̀ sí i
Àpàtà ìgbàlà wa.
Ẹ jẹ́ k' á wá síwájú Rẹ,
Pẹ̀lú 'yìn àt' ọpẹ́;
K' á kọrin oore-ọ̀fẹ́ Rẹ,
K' á sì yọ̀ ayọ̀ nlá.
Ọlọ́run yìí tóbi l' Ọba
J' àwọn òrìṣà lọ;
Gbogbo ayé wà ní 'kàwọ́ Rẹ,
Àt' àwọn òkè nlá.
Tìrẹ ni àwọn òkun nlá,
Òun l' Ẹlẹ́dàá wọn;
Àti 'yangbé ilẹ̀ pẹ̀lú,
Ọwọ́ Rẹ̀ l' ó dá wọn.
Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a wolé,
K' á kúnlẹ̀ n' wájú Rẹ̀;
K' á b' Ẹlẹ́dàá àt' Ọba wa,
K' á gb' ohùn Rẹ̀ lónì.