Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 488: Oore-ọ̀fẹ́ Kríst' Olúwa

May The Grace Of Christ Our Saviour

Oore-ọ̀fẹ́ Kríst' Olúwa
Ìfẹ́ Bàbá àìlópin,
Ojú-rere Ẹ̀mí Mímọ́,
K' ó t' òkè bà s' orí wa.

Báyìí l' a lè máa jùmọ̀ gbé
N' ìrẹ́pọ̀ n' nú Olúwa;
K' a sì lè ní 'dàpọ̀ dídùn,
Àt' ayọ̀ t' ayé kò ní.
Àmín.