Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 482: Ẹ̀yin Ìjọ Ọlọ́run
You The Church Of God
Ẹ̀yin ìjọ Ọlọ́run,
Ẹ mú 'dámẹ́wá yín wá,
Ẹ mú 'dámẹ́wá àt' ọrẹ yín
Wá f' Olúwa.
Àṣẹ Olúwa wa ni,
Ó pèsè 'bùkún f' àwọn
T' ó bá j' olóòótọ́ nínú sísán
'Dámẹ́w' àt' ọrẹ.
Ìbùkún fún yín n' ilé,
Ìbùkún fún yín l' oko,
Ìbùkún fún yín níbi gbogbo
Tí ẹ bá ń lọ.