Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 481: Ohun T' A À Fi Fún Ọ

We Give Thee But Thine Own

Ohun t' a à fi fún Ọ
Tirẹ ni Olúwa,
Gbogbo ohun tí a sì ní;
Ọwọ́ Rẹ̀ l' ó ti wá,

Jẹ́ k' a gbà ẹ̀bùn Rẹ̀
Bí ìríjú rere,
Bí O sì ti ń búkún wa tó,
Bẹ́ẹ̀ l' a ó fi fún Ọ.

Ọ̀pọ̀ ni iṣẹ́ ń ṣe
Tí wọ́n kò r' oúnjẹ jẹ;
Ọ̀pọ̀ l' ó sì ti ṣako lọ
Kúrò l' àgbo Jésù.

K' a máa tù ni nínú,
K' a máa rẹ ni l' ẹkún,
K' a máa bọ́ aláìní-bàbá,
N' iṣẹ́ t' a á bá máa ṣe.

A gbà ọ̀rọ̀ Rẹ̀ gbọ́
Búsì ìgbàgbọ́ wa;
Ohun t' a a ṣe fún ẹni Rẹ̀
Jésù, a ṣe é fún Ọ.