Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 480: Jésù F' Ara Hàn Ní Tòótọ́

Jesus Truly Manifested Himself

Jésù f' ara hàn ní tòótọ́
Níbi àṣẹ 'yàwó;
Olúwa, àwa bẹ̀ Ọ, wá,
F' ara Rẹ̀ hàn níhìn-ín.

Fi ìbùkún Rẹ̀ fún àwọn
Tí ó dàwọ́ pọ̀ yìí,
F' ojú rere wò 'dàpọ̀ wọn,
Sì bùkún ẹ̀jẹ́ wọn.

F' ẹ̀bùn ìfẹ́ kún ayà wọn,
Fún wọn n' ìtẹ́lọ́rùn;
Fi àlááfíà Rẹ̀ fún wọn,
Sì bùsí iní wọn.

F' ìfẹ́ mímọ́ sọ wọn d' ọkan,
Kí wọn fífẹ́ Krístì
Mú àníyàn ilé fẹ́rẹ̀,
Nípa àjùmọ̀ ṣe.

Jẹ́ kí wọn rán 'ra wọn lọ́wọ́,
Nínú ìgbàgbọ́ wọn;
Kí wọn sì ní ọmọ rere,
Tí yóò gbé 'lé wọn rò!
Àmín.