Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 48: Ọlọ́run Àwa Fẹ́ Ilé T' Ọlá Rẹ̀ Wà

We Love the Place

Ọlọ́run, àwa fẹ́
Ilé t' ọlá Rẹ wà;
Ayọ̀ ibùgbé Rẹ̀
Jù ayọ̀ ayé lọ.

Ilé àdúrà ni,
Fún àwọn ọmọ Rẹ;
Jésù, Ó wà níbẹ̀.
Láti bá wa padé.

A fẹ́ ọ̀rọ̀ ìyè,
Tí ń sọ t' àlááfíà,
T' ìtùnú n' nú ìjà,
Àt' ayọ̀ tí kì í tán.

A fẹ́ kọrin àánú
T' á ń rí gbà l' ayé yìí;
Ṣùgbọ́n àwa ń' fẹ́ mọ̀
Orin 'ṣẹ́gun t' ọ̀run.

Jésù, fún wa n' ìpa,
K' á fẹ́ Ọ sí i l' ayé,
K' á r' ojú Rẹ̀ l' ọ̀run,
K' á b' àwọn mímọ́ sìn.