Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 479: Sìmí Lé Olúwa

Rest In Lord

Sìmí lé Olúwa, ẹ gbọ́
Orin dùùrù ọ̀run;
Sìmí lé Ìfẹ́ àìlópin,
Sì dúró jẹ̀ẹ́.

Sìmí ìwọ ọkọ t' ọ̀gbà,
Ìyàwó rẹ lónìí nínú Jésù
'yàwó rẹ ni
Títí ayé.

Ìwọ tí a fà ọwọ́ rẹ
F' ọkọ n' nú ilé yìí,
Sìmí, Bàbá f' èdìdì Rẹ̀
S' ìlérí yín.

Ẹ sìmí, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ wọn
T' ẹ ẹ wá bá wọn pé jọ;
Ọlọ́run wọn, àti ti yín,
Gbà ohùn wọn.

Sìmí: Jésù ọkọ ìjọ
Dúró ti yín níhìn-ín;
Nínú ìdàpọ̀, ó ń fà,
Ìjọ mọ́ 'ra.

Ẹ sìmí: Àdàbà Mímọ́,
Ṣiṣẹ́ Rẹ̀ nínú wa;
Sìmí lé ìfẹ́ àìlópin
Sì dúró jẹ̀ẹ́.