Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 477: Bàbá, Àwa Gbé Ọkàn
We Lift Our Hearts, O Father
Bàbá, àwa gbé ọkàn
Àt' ohùn wa sí Ọ,
Fún ìránṣẹ́ Rẹ̀ wọ̀nyí
Ní àdúrà àt' ìyìn,
Ìyìn fún ayọ̀ fífẹ́,
Àwọn ayọ̀ t' òkè,
Ìyìn 'bùkún àìníye
Àti ìfẹ́ s' ìfẹ́.
Àdúrà kí ìtúùbà
Tòótọ́ lè di pípé,
K' ọkan d' ara èkejì
Kí wọn j' ọkan n' nú Rẹ̀;
Àdúrà k' ìdàpọ̀ wọn
Lè jẹ́ tímọ́tímọ́,
Gẹ́gẹ́ bí 'dè tí ó sọ
Krístì mọ́ ìjọ Rẹ̀
Àdúrà k' ìlérí yìí
Lè j' àṣepé n' pá Rẹ̀,
Sì f' ìbùkún tí kì í tán
Sí ọdún ayé wọn,
Ìyìn 'rètí t' ó l' ògo
T' ó r' ẹ̀hìn ìkélé
Níb' ìgbàgbọ́ gbé fò lọ.
Níb' ìfẹ́ kìí í yẹ láé.