Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 476: Ìre T' A À Sú Ní Eden
The Voice That Breathed O'er Eden
Ìre ta à sú ní Eden,
Ní 'gbéyàwó kín-ín-ni
Ìbùkún ta a búkún wọn,
Ó wà síbẹ̀ síbẹ̀.
Síbẹ̀ títí di oní,
N' ìgbéyàwó Kristẹn;
Ọlọ́run wà láàrín wa,
Láti súre fún wa.
Ìre kí wọn lè máa bí,
Kí wọn sì lè máa rè;
Kí wọn n' ìdàpọ̀ Mímọ́,
T' ẹnìkan kì yóò lè tú.
Bá ni pè Bàbá, sì fà
Obìnrin yìí f' ọkọ;
Bí O ti fi Eefa fún
Adam l' ọjọ́ kín ni.