Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 475: Ìpè Náà Ti Dùn Tó

How Welcome Was The Call

Ìpè náà ti dùn tó,
Ọjọ́ ayọ̀ sì ni,
Nígbà tí Jésù, ní Kánà,
Búkún 'gbéyàwó náà.

Jésù Bàbá ìfẹ́,
Sọ̀ kalẹ̀ wá lónìí;
Láti fún wa ní 'bùkún Rẹ̀,
Tí kì yóò tán láéláé.

Tú bùkún Rẹ̀ s' orí,
Ọkọ àt' aya yìí,
Ìbùkún tí ó ń sàn jáde,
Láti 'hà Rẹ̀, Jésù.

Bá wa p' Ẹ̀mí Mímọ́
Àánú yìí l' a ń tọrọ;
Bí O ti sọ wọ́n pọ̀ s' ọkan
Búkún wọn títí láé.