Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 474: 'Gbà T' A Bá Bá Jésù Dúró N' Ilé Ìbùkún Ni
When We Stand With Jesus In That Blessed Home
'Gbà t' a bá bá Jésù dúró n' ilé ìbùkún ni
Tí ọjọ́ ìrìn-àjò wa yóò pín;
Àwa yóò hà rántí ìyà tí a ti jẹ rí bí?
Tàb' a ó rántí a ó rántí ìbànújẹ́ ayé yìí?
Àwa kì yóò rántí gbogbo ìṣòro wa rárá
Nígbà t' a a bá ti parí iṣẹ́ wa l' ayé yìí,
Nígbà tí a bá ti f' adé ìyè dé wa lórí,
Ohun gbogbo l' a ó gbàgbé l' oj' ayọ̀ náà.
Nígbà tí a bá fi ọrọ̀ ìjọba náà hàn wa.
T' Ọba sì pè wa láti pín n' ayọ̀ Rẹ̀;
Àwa yóò hà lè fi ìbànújẹ́ tí ayé yìí
Wé ọrọ̀ ògo tí ìjọba ọ̀run?
Àwa kì yóò rántí gbogbo ìṣòro wa rárá
Nígbà t' a a bá ti parí iṣẹ́ wa l' ayé yìí,
Nígbà tí a bá ti f' adé ìyè dé wa lórí,
Ohun gbogbo l' a ó gbàgbé l' oj' ayọ̀ náà.
Nígbà tí a bá rí àwọn tí a ti ránlọ́wọ́,
Tí wọ́n dúró yí ìtẹ́ Ọlọ́run ká
Ṣ' a ó k' àbámọ̀ àkókò t' a a lọ láti rán wọn lọ́wọ́?
Tàb' a ó kẹ́gàn ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀?
Àwa kì yóò rántí gbogbo ìṣòro wa rárá
Nígbà t' a a bá ti parí iṣẹ́ wa l' ayé yìí,
Nígbà tí a bá ti f' adé ìyè dé wa lórí,
Ohun gbogbo l' a ó gbàgbé l' oj' ayọ̀ náà.