Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 473: Gbàt' Àjò Mi Bá Pín

When My Life Work Is Ended

Gbàt' àjò mi bá pín, tí mo gòkè odò ayé,
Tí ara ikú yìí sì gbé àìkú wọ,
Èm' ó mọ Olùgbàlà mi lódì kejì odò,
Òun pàápàá ni yóò kọ̀ kí mi kú àbò.

Èm' ó mọ On, èm' ó mọ On.
Lọ́dọ̀ Rẹ̀ l' èmi ó sì dúró;
Èm' ó mọ On, èm' ó mọ On,
Nípa àmì iṣọ́ ọwọ́ Rẹ̀.

A! Ìrètí ìbùkún, 'gbà tí mo bá r' ojú Rẹ̀,
Àti gbogbo dídan ògo ẹwà Rẹ̀;
Ọkàn mi y' ó f' ìyìn fún Un f' ọ̀pọ̀ oor'-ọ̀fẹ́ Rẹ̀,
Tí Ó pèsè ibùgbé fún mi l' òkè.

Èm' ó mọ On, èm' ó mọ On.
Lọ́dọ̀ Rẹ̀ l' èmi ó sì dúró;
Èm' ó mọ On, èm' ó mọ On,
Nípa àmì iṣọ́ ọwọ́ Rẹ̀.

A! èmi yóò rí àwọn wọn-ọn-ni tí mo ti fẹ́
Tí wọ́n ti fi ayé òṣì yìí sílẹ̀;
Níbi 'simi ọgbà Edẹni a kì yóò pínyà láé.
Ṣùgbọ́n mo kó fẹ́ rí Olúwa mi ná.

Èm' ó mọ On, èm' ó mọ On.
Lọ́dọ̀ Rẹ̀ l' èmi ó sì dúró;
Èm' ó mọ On, èm' ó mọ On,
Nípa àmì iṣọ́ ọwọ́ Rẹ̀.

Láàrín 'bòdè ìlú, nínú aṣọ ọgbọ̀ funfun,
Yóò sìn mi dé ibi tí ẹkún kò sí;
Inú mi yóò dùn pẹ̀lú orin ayérayé,
Ṣùgbọ́n mo kó fẹ́ rí Olúwa mi náà.

Èm' ó mọ On, èm' ó mọ On.
Lọ́dọ̀ Rẹ̀ l' èmi ó sì dúró;
Èm' ó mọ On, èm' ó mọ On,
Nípa àmì iṣọ́ ọwọ́ Rẹ̀.