Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 472: Gbọ́ Ọkàn Mi

Hark! Hark, My Soul!

Gbọ́ ọkàn mi,
Bí Ángẹ́lì ti ń kọrin
Yíká ọ̀run àti yíká ayé;
Ẹ gbọ́ bí ọ̀rọ̀ orin wọn ti dùn tó!
Tí ń sọ 'gbà tí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò sí mọ́!

Ángẹ́lì Jésù, ángẹ́l' mọ́lẹ̀,
Wọ́n ń kọrin ayọ̀ padé èrò l' ọ̀nà.

Bá a sì ń lọ bẹ́ẹ̀ l' a sì ń gbọ́ orin wọn
'Wá, alààrẹ̀, Jésù l' Ó ní k' ẹ ẹ wá;
L' òkùnkùn ni a ń gbọ́ orin dídùn wọn
Ohùn orin wọn ni ń f' ọ̀nà hàn wa.

Ángẹ́lì Jésù, ángẹ́l' mọ́lẹ̀,
Wọ́n ń kọrin ayọ̀ padé èrò l' ọ̀nà.

Ohùn Jésù ni a ń gbọ́ l' ọ̀nà rere;
Ohùn náà ń dún b' agogo y' ayé ká,
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn t' ó gbọ́ ni sì ń bọ̀;
Mú wọn w' ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Olùgbàlà wa.

Ángẹ́lì Jésù, ángẹ́l' mọ́lẹ̀,
Wọ́n ń kọrin ayọ̀ padé èrò l' ọ̀nà.

Máa kọrin ń sọ, ẹ̀yin Ángẹ́lì rere.
Ẹ máa kọrin dídùn, k' a a bàá máa gbọ́;
Tít' a ó fi 'nú omijé ojú wa nù;
Tí a ó sì máa yọ títí láéláé.

Ángẹ́lì Jésù, ángẹ́l' mọ́lẹ̀,
Wọ́n ń kọrin ayọ̀ padé èrò l' ọ̀nà.