Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 471: Ẹ̀yin Èrò
Whither Pilgrim
Ẹ̀yin èrò níbo l' ẹ ń lọ
T' ẹ̀yin t' ọ̀pá lọ́wọ́ yín?
A ń rìn àjò mímọ́ kan lọ,
Nípa àṣẹ Ọba wa.
Lórí òkè oun pẹ̀tẹ́lẹ̀
A ń lọ s' ààfin Ọba rere,
A ń lọ s' ààfin Ọba rere,
A ń lọ s' ilé t' ó dára.
A ń lọ s' ààfin Ọba rere,
A ń lọ s' ilé t' ó dára.
Ẹ̀yin èrò, ẹ sọ fún ni
T' ìrètí tí ẹ̀yin ní?
Aṣọ Mímọ́, adé ògo
Ni Jésù yóò fi fún wa;
Omi ìyè l' a ó máa mu;
A ó sì b' Ọlọ́run wa gbé,
A ó sì b' Ọlọ́run wa gbé,
N' ilé Mímọ́ dídára,
A ó sì b' Ọlọ́run wa gbé
N' ilé Mímọ́ dídára,
Ẹ kò bẹ̀rù ọ̀nà t' ẹ ẹ ń rìn
Ẹ̀yin èrò kékeré?
Ọ̀rẹ́ aìrí ń pẹ̀lú wa lọ,
Àwọn Ángẹ́lì yí wa ká,
Jésù Krístì l' àmọ̀nà wa
Yóò máa ṣọ́ wa, yóò máa tọ́ wa,
Yóò máa ṣọ́ wa, yóò máa tọ́ wa,
Nínú ọ̀nà àjò wa,
Yóò máa ṣọ́ wa, yóò máa tọ́ wa,
Nínú ọ̀nà àjò wa.
Èrò, a lè bá yín kẹ́gbẹ́
L' ọ̀nà àjò s' ilé náà?
Wá sí ẹgbẹ́ èrò wa, wá
Ẹ má ṣe fi wa sílẹ̀,
Jésù ń dúró, Ó ń rètí wa,
Jésù ń dúró, Ó ń rètí wa,
N' ilé mímọ́ t' ó dára,
Jésù ń dúró, Ó ń rètí wa,
N' ilé mímọ́ t' ó dára.