Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 470: Láàrín 'Yèméjì Àt' Àrò
Through The Night Of Doubt And Sorrow
Láàrín 'yèméjì àt' àrò,
L' àwa ọwọ́ èrò ń lọ,
A ń kọrin ìrètí ògo,
A ń tọ lọ sí 'lẹ̀ 'lérí.
Kédéré níwájú wa ni
Ìmọ́lẹ̀ Àtọ́nà hàn
Pẹ̀lú ìfọwọ́sọ̀ wọ pọ̀.
Àwa ń f' ìgboyà yàn lọ.
Ọlọ́run ń b' àwa èrò lọ,
'Mọ́lẹ̀ Rẹ̀ f' ayọ̀ fún wa,
Ó lé 'bànújẹ́ lọ fún wa,
Ó f' ayọ̀ sí ọ̀nà wa.
Èrèd' ìrìn àjò wa, ni,
Ìgbàgbọ́ tí kò lè yẹ;
Ìrètí wa tí ó l' ògo wa.
Àt' òdodo Ọba wa.
Ìgbà ayọ̀ náà fẹ́rẹ̀ dé,
T' a a ó sì 'bojì gbogbo,
A ó f' òpin sí iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
Wàhálà yóò sì d' òpin.