Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 47: Olúwa Àwa Péjọ

Lord, We Come before Thee Now

Olúwa àwa péjọ,
A wá wolé lẹ́sẹ̀ Rẹ,
A, má ṣàì k' ẹ̀bẹ̀ wa sí
A ó ha wá Ọ lásán bí?
A ó ha wá Ọ lásán bí?

Jésù 'Wọ l' á gbẹ́kẹ̀lé;
Jọ̀ọ́, wá nínú àánú Rẹ
F' oore nlá kún ọkàn wa,
Jẹ́ k' etè wa máa yìn Ọ
Jẹ́ k' etè wa máa yìn Ọ

Olúwa bá wa sọ̀rọ̀
Èyí ló lè m' ayọ̀ wa;
Jẹ́ k' olúkúlùk' ọkàn
Gbà ìgbàlà kíkún náà
Gbà ìgbàlà kíkún náà.

Ṣìpè f' àwọn tí ń sọkún
M' àkókò ayọ̀ wọn dé;
Gb' àwọn t' ó ṣubú dìde
Sọ gbàgbọ́ wọn di pípé
Sọ gbàgbọ́ wọn di pípé.

Jẹ́ gbogbo wa wá Ọ rí
'Wọ Ọlọ́run Olóore,
Dá àwọn ondè sílẹ̀;
K' á lè máa yọ̀ nínú Rẹ
K' á lè máa yọ̀ nínú Rẹ.