Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 469: Láìpẹ́ Àwa Yóò Lọ S' Ilé
In A Little While We're Going Home
Ẹ jẹ́ k' a a kọrin tí yóò mú inú wa dùn,
Láìpẹ́ àwa yóò lọ sílé;
Òru yóò kọjá ní ọjọ́ ayérayé
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé;
Láìpẹ́ ọjọ́, láìpẹ́ ọjọ́
A ó là ìṣòro kọjá;
Àwa yóò padé, nígbà t' ìjì bá kọjá,
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé.
A ó ṣe iṣẹ́ t' ọwọ́ wa bá láti ṣe,
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé;
Ògo Ọlọ́run yóò fún wa ní agbára
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé.
Láìpẹ́ ọjọ́, láìpẹ́ ọjọ́
A ó là ìṣòro kọjá;
Àwa yóò padé, nígbà t' ìjì bá kọjá,
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé.
A ó t' ọ̀nà ṣe fún arìnrìn-àjò t' ó rẹ̀,
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé;
Jẹ́ k' a tàn ìhìn-rere náà ká gbogb' ayé,
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé.
Láìpẹ́ ọjọ́, láìpẹ́ ọjọ́
A ó là ìṣòro kọjá;
Àwa yóò padé, nígbà t' ìjì bá kọjá,
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé.
Ìsimi ń bẹ fún gbogbo ọkàn tí ń ṣ' ààrẹ̀
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé;
Ẹkún kì yóò sí nínú ìlú dídan náà
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé.
Láìpẹ́ ọjọ́, láìpẹ́ ọjọ́
A ó là ìṣòro kọjá;
Àwa yóò padé, nígbà t' ìjì bá kọjá,
Láìpẹ́ àwa yóò lọ s' ilé.