Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 468: Lẹ́hìn Ọdún Díẹ̀

A Few More Years Shall Roll

Lẹ́hìn ọdún díẹ̀,
Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀,
Àwa yóò wà pẹ̀lú àwọn
Tí wọ́n sùn n' ibojì,
Olúwa mú mi yẹ
Fún ọjọ́ ńlá ńlá náà
Jọ̀ọ́ wẹ̀ mi nínú ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀,
Sì kó ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.

Lẹ́hìn ìjì díẹ̀,
L' ayé búrúrú yìí
A ó dé ibi ìjì dẹ́kun,
Tí ìrúmi kò sí
Olúwa mú mi yẹ
Fún ọjọ́ ńlá ńlá náà
Jọ̀ọ́ wẹ̀ mi nínú ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀,
Sì kó ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ!

Lẹ́hìn 'yọ̀nú díẹ̀,
Lẹ́hìn 'pínyà díẹ̀;
Lẹ́hìn iṣẹ́ oun omijé,
A kì yóò sọkún mọ́,
Olúwa mú mi yẹ
Fún ọjọ́ 'bùkún náà
Jọ̀ọ́ wẹ̀ mi nínú ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀,
Sì kó ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ!

Ọjọ́ díẹ̀ l' ó kù
Òun yóò tún padà wá,
Ẹni t' ó kú k' àwa lè yè.
K' a a bàá lè bá A jọba.
Olúwa mú mi yẹ
Fún ọjọ́ ayò náà
Jọ̀ọ́ wẹ̀ mi nínú ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀,
Sì kó ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ!