Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 467: Kríst Balógun Wa Níwájú Ogun

Christ, Our Mighty Captain, Lead Against The Foe

Kríst Balógun wa níwájú ogun,
B' Ó bá rán wa ní ṣe a kò ní bẹ̀rù;
Bí ohun t' Ó fẹ́ ṣe kò tilẹ̀ yé wa,
Síbẹ̀ a ó tẹ̀lé E títí.

Tẹ̀ sí 'wájú! l' àṣẹ Olúwa,
Tẹ̀ sí 'wájú! sí 'lẹ̀ 'lérí náà
Tẹ̀ sí 'wájú! kọ orin s' òkè,
Pẹ̀lú Krístì ìṣẹ́gun dájú.

Gbogbo ìfẹ́jú Èṣù kò lè mí wa,
Bí Krístì jẹ́ àsà àt' àpáta wa;
A ó máa fi ìdà-ẹ̀mí bí a ti ń lọ.
A ó máa tẹ̀lé E títí.

Tẹ̀ sí 'wájú! l' àṣẹ Olúwa,
Tẹ̀ sí 'wájú! sí 'lẹ̀ 'lérí náà
Tẹ̀ sí 'wájú! kọ orin s' òkè,
Pẹ̀lú Krístì ìṣẹ́gun dájú.

Ẹ jẹ́ kí a gbé àsíá wa sókè,
Ibi kò lè dé ibi tí Ó bá wa;
Krístì Balógun wa ti ṣẹ́gun ayé
A ó máa tẹ̀lé E títí

Tẹ̀ sí 'wájú! l' àṣẹ Olúwa,
Tẹ̀ sí 'wájú! sí 'lẹ̀ 'lérí náà
Tẹ̀ sí 'wájú! kọ orin s' òkè,
Pẹ̀lú Krístì ìṣẹ́gun dájú.

B' ogun náà tilẹ̀ le, kò ní pẹ́ parí,
Nígbà náà a ó dàpọ̀ pẹ̀l' àwọn mímọ́;
Láti fi ayọ̀ kọ orin ìṣẹ́gun,
Bí a bá tẹ̀lé E títí.

Tẹ̀ sí 'wájú! l' àṣẹ Olúwa,
Tẹ̀ sí 'wájú! sí 'lẹ̀ 'lérí náà
Tẹ̀ sí 'wájú! kọ orin s' òkè,
Pẹ̀lú Krístì ìṣẹ́gun dájú.