Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 466: Mo Ń Tẹ̀ Síwájú N' Gbà Gbogbo
I'm Pressing On The Upward Way
Mo ń tẹ̀ síwájú n' gbà gbogbo,
Ní ìrìn àjò mi s' ọ̀run;
Bí mo ti ń lọ, mo ń gbàdúrà
S' Olúwa fún 'tẹ̀ síwájú.
Jọ̀ọ́ gbé mi sókè, Olúwa,
Sí ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀run;
Olúwa, fi ẹsẹ̀ mi lé
Bí gíga jù tí ṣáájú lọ.
Ọkàn mi kò fẹ́ dúró ní
Ibi 'yèméjì àt' ẹ̀rù
Àwọn mìí ń gbé n' ibi wọ̀nyí,
Kí n tẹ̀ síwájú l' àdúà mi.
Jọ̀ọ́ gbé mi sókè, Olúwa,
Sí ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀run;
Olúwa, fi ẹsẹ̀ mi lé
Bí gíga jù tí ṣáájú lọ.
Mo fẹ́ gbé ga jù ayé lọ,
Ọkọ̀ Èṣù kò lè ṣe ǹkan,
Tórí 'gbàgbọ́ fi 'ró orin
Ayọ̀ àwọn mímọ́ fún mi.
Jọ̀ọ́ gbé mi sókè, Olúwa,
Sí ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀run;
Olúwa, fi ẹsẹ̀ mi lé
Bí gíga jù tí ṣáájú lọ.
Mo fẹ́ gun òkè gíga náà
Kí n rí títayọ̀ ògo rẹ̀;
Títí n ó d' ọ̀run, mo ń gbàdúà
K' Ọba mú mi dé 'lé gíga
Jọ̀ọ́ gbé mi sókè, Olúwa,
Sí ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀run;
Olúwa, fi ẹsẹ̀ mi lé
Bí gíga jù tí ṣáájú lọ.