Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 465: N Ó Tẹ̀lé Ọ Olùgbàlà
I Will Follow Thee My Saviour
N ó tẹ̀lé Ọ, Olùgbàlà,
Bó ti wù k' ìpín mi rí,
N' ibikíbi tí O bá ń lọ,
Olúwa, n ó tẹ̀lé Ọ.
N ó tẹ̀lé Ọ, Olùgbàlà,
Ó t' ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ lẹ̀ fún mi,
Bí gbogb' èèyàn kọ Ọ sílẹ̀
N' p' oor-ọ̀fẹ́ n ó tẹ̀lé Ọ.
B' ọ̀nà náà tilẹ̀ ní ẹgún
Tí kò l' ọ̀nà bí okun,
'Wọ ti rìn 'nà yìí ṣáájú mi,
N ó sì f' ayọ̀ tẹ̀lé Ọ.
N ó tẹ̀lé Ọ, Olùgbàlà,
Ó t' ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ lẹ̀ fún mi,
Bí gbogb' èèyàn kọ Ọ sílẹ̀
N' p' oor-ọ̀fẹ́ n ó tẹ̀lé Ọ.
Bí mo tilẹ̀ rí ìpọ́njú
T' a á sì dán mi wò kíkán
Mo rántí pé a dán Ọ wò rí
Mo yọ láti tẹ̀lé Ọ.
N ó tẹ̀lé Ọ, Olùgbàlà,
Ó t' ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ lẹ̀ fún mi,
Bí gbogb' èèyàn kọ Ọ sílẹ̀
N' p' oor-ọ̀fẹ́ n ó tẹ̀lé Ọ.
Bí O mú mi kọjá 'pọ́njú,
Tí a sì kọ mi sílẹ̀,
A ti kọ Ìwọ sílẹ̀ rí,
N ó sì tẹ̀lé 'ṣiṣẹ́ Rẹ̀.
N ó tẹ̀lé Ọ, Olùgbàlà,
Ó t' ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ lẹ̀ fún mi,
Bí gbogb' èèyàn kọ Ọ sílẹ̀
N' p' oor-ọ̀fẹ́ n ó tẹ̀lé Ọ.
Bí ìwọ tilẹ̀ mú mi lọ
S' ib' odò rírú Jordan,
O ti là á kọjá ṣáájú mi.
Síbẹ̀ èm' ó tẹ̀lé Ọ.
N ó tẹ̀lé Ọ, Olùgbàlà,
Ó t' ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ lẹ̀ fún mi,
Bí gbogb' èèyàn kọ Ọ sílẹ̀
N' p' oor-ọ̀fẹ́ n ó tẹ̀lé Ọ.