Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 463: Fọn Ìpè Ogun
Sound The Battle Cry
Fọn ìpè ogun, ọ̀tá fẹ́rẹ̀ẹ dé,
Ẹ múra ìjà, f' Olúwa
Ẹ dìde gírí, dì àmúrè yín;
Ẹ gbékẹ̀ yín lé 'tọ̀sọ́nà Rẹ̀.
Ẹ sí ogun, dìde, bọ̀ s' ojú 'jà
Dìde, múra; kígbe náà kíkán,
Tẹ̀ síwájú, Kígbe pé Hosana!
Krístì ni Balógun, ẹgbẹ́ wa.
A ń tẹ̀ síwájú pẹ̀lú agbára,
Ó dá wa l' ojú p' a ó ṣẹ́gun;
Ohun ìjà wa, àsà àt' àsíá
B' a ń jà f' òtítọ́ a kì yóò bakú.
Ẹ sí ogun, dìde, bọ̀ s' ojú 'jà
Dìde, múra; kígbe náà kíkán,
Tẹ̀ síwájú, Kígbe pé Hosana!
Krístì ni Balógun, ẹgbẹ́ wa.
Ọlọ́run wa, gbọ́ 'gbà t' a bá pè Ọ
Jẹ́ kí 'rànwọ́ Rẹ̀ kárí wa,
'Gb' ogun bá parí, t' a bá sì ṣẹ́gun,
Fún gbogbo wa l' adé ìyè Rẹ̀.
Ẹ sí ogun, dìde, bọ̀ s' ojú 'jà
Dìde, múra; kígbe náà kíkán,
Tẹ̀ síwájú, Kígbe pé Hosana!
Krístì ni Balógun, ẹgbẹ́ wa.