Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 462: A! Ẹgbẹ́ Mi, Ẹ W' Àsíá

Hold The Fort

A! ẹgbẹ́ mi, ẹ w' àsíá.
B' ó ti ń fẹ́ lélé!
Ogun Jésù fẹ́rẹ̀ dé ná
A fẹ́rẹ̀ ṣẹ́gun,

D' odi mú, Èmi fẹ́rẹ̀ẹ dé,
Bẹ́ẹ̀ ni Jésù wí,
Rán 'dáhùn padà s' ọ̀run pé,
Àwa yóò dì í mú.

Wò àwọn akọni ayé,
Èṣù ń kó wọn bọ̀;
Àwọn alágbára ń ṣubú
Ìdààmú dé tán,

D' odi mú Èmi fẹ́rẹ̀ẹ dé,
Bẹ́ẹ̀ ni Jésù wí,
Rán 'dáhùn padà s' ọ̀run pé,
Àwa yóò dì í mú.

Wò b' àsíá ògo ti ń fẹ́!
Gbọ́ ohùn ìpè!
L' orúkọ Jésù, Balógun,
Àwa yóò ṣẹ́gun

D' odi mú Èmi fẹ́rẹ̀ẹ dé,
Bẹ́ẹ̀ ni Jésù wí,
Rán 'dáhùn padà s' ọ̀run pé,
Àwa yóò dì í mú.

B' ìjà náà tilẹ̀ pẹ́ parí,
Ìrànwọ́ wa ń bọ̀,
Balógun wa ń bọ̀ wá tètè
A, ẹ hó f' ayọ̀.

D' odi mú Èmi fẹ́rẹ̀ẹ dé,
Bẹ́ẹ̀ ni Jésù wí,
Rán 'dáhùn padà s' ọ̀run pé,
Àwa yóò dì í mú.