Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 461: A Wà Wà Láàyé, A Sì Ń Gbé

We Are Living, We Are Dwelling

A wà wà láàyé, a sì ń gbé
L' àkókò t' ó kún f' ẹ̀rù;
Ìgbà ń dé, ìgbà ń sọ wípé
Wíwà láàyé ni ọlá.
Gbọ́! jí dìde orílẹ̀-èdè,
Gbogbo wọn lọ sí ogun;
Gbọ́! kín ni hà ń dún?
Ẹ̀dá hà ń kẹ́rọ̀rà ìkẹ̀hìn bí?

Kristẹn gb' ohun ìjà rẹ wọ,
Múra fún ìjà ńlá náà;
Dé àsí-borí ìgbàlà,
Sì mú àsà 'hìnrere;
Gbé aṣọ àlááfíà wọ,
Mú ìdà Ẹ̀mí lọ́wọ́;
Jáde pẹ̀lú 'gboyà láti
Dúró n' nú 'pa Jèhófà.

B' ẹ̀mí búburú yí ọ ká,
Tí í ṣe ọ̀tá Ọlọ́run;
Ọba alágbára jùlọ
Wọ́n ń rìn kààkiri láìrí;
Wọ́n kó ara wọn jọ s' ogun,
Wọ́n ń múra fún 'jà kẹ̀hìn,
Kristẹni máa múra, máa ṣọ́nà,
Jà b' ọkùnrin fún 'gbàlà

Kristẹn dìde jà n' ogun yìí
Máa jà tít' o ó fi ṣẹ́gun;
Tít' Ọ̀gágun yóò fi wípé,
Ó ṣeun ọm' ọ̀dọ̀ rere!
Ẹni tí o bá j' olóòótọ́
T' ó sì forítì í d' òpin,
Ni yóò jogún 'yè àìlópin
Tí a ti ṣe 'lérí rẹ̀.