Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 460: Tani Ń Ṣe T' Olúwa

Who Is On The Lord's Side?

Tani ń ṣe t' Olúwa?
Tani y' ó sìn 'Ba?
Tani yóò rán-an lọ́wọ́
Láti gb' ẹmí là?
Tani yóò kọ ayé,
K' ó dojú k' ọ̀tá?
Tani ń ṣe t' Olúwa
Tí yóò jí ṣe fún Un?
Nípa ìpè àánú
Nípa oor'-ọ̀fẹ́,
T' Olúwa l' àwa ń ṣe;
Ti Olùgbàlà.

Kì í ṣe 'torí ògo,
Adé àt' opé,
L' a fi d' ọmọ-ogun,
T' a ń kọrin ogun;
Ṣùgbọ́n fún ìfẹ́ t' Ó ń
P' àwọn t' Ó kú fún,
Ẹni Jésù bá pè
Yóò ṣe t' Olúwa;
Nípa 'fẹ́ mímọ́ Rẹ̀,
Nípa oor' ọ̀fẹ́,
T' Olúwa l' àwa ń ṣe;
Ti Olùgbàlà.

Jésù, kì í ṣe wúrà
Ni Ó fi rà wá;
Ó f' ẹ̀mí Rẹ̀ rà wá,
Láti fi ṣ' ọ̀ṣọ́
'Wọ f' ìbùkún Rẹ̀ kún
Ẹni tó Ọ wá
'Wọ fún wa ní ìfẹ́
Àt' òmìnira,
Nípa ìràpadà,
Nípa oor'-ọ̀fẹ́,
T' Olúwa l' àwa ń ṣe;
Ti Olùgbàlà.

Ìjà lè le kíkán
Ọ̀tá lè tàágun,
Kò s' ẹni lè borí
Ogun Ọba wa.
Lábẹ́ àsíá Rẹ̀
Ìṣẹ́gun dájú,
Nítorí òótọ́ Rẹ̀,
Yóò borí dandan,
Pẹ̀l' ayọ̀ l' a ó jọ́sìn,
Nípa oor'-ọ̀fẹ́,
T' Olúwa l' àwa ń ṣe;
Ti Olùgbàlà.