Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 46: Ọjọ́ Ń Rẹ 'B' Àtìwọ̀ Rẹ̀
Day Is Dying In The West
Ọjọ́ ń rẹ 'b' àtìwọ̀ rẹ̀
Ọ̀run ń mú sìmí rẹ̀ wá;
Dúró sìn Olúwa rẹ.
Gb' alẹ́ ń tàn fìtílà rẹ;
Lójú sánmọ̀.
Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́!
Olú ọ̀run
Ọ̀run, ayé ń jubà Rẹ
Ọ̀run àt' ayé ń yìn Ọ
Ọ̀gá ọ̀gọ́.
Olúwa 'yé kó gbogbo
Àwa tí ń wò ojú Rẹ̀
Sínú àgbò ìfẹ́ Rẹ
Láti pà wá mọ́ títí,
'Wọ wa ń tọ́sí.
Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́!
Olú ọ̀run
Ọ̀run, ayé ń jubà Rẹ
Ọ̀run àt' ayé ń yìn Ọ
Ọ̀gá ọ̀gọ́.
Ojìjì alẹ́ bò 'lẹ̀,
Ọ̀kùn 'fẹ́ Rẹ dì wá mú,
Nínú ọ̀gọ́-àt' ẹwà 'wọn
Ìràwọ̀ t' ó bojú Rẹ,
L' ọkàn wa ń wò.
Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́!
Olú ọ̀run
Ọ̀run, ayé ń jubà Rẹ
Ọ̀run àt' ayé ń yìn Ọ
Ọ̀gá ọ̀gọ́.
Gbà tí ọ̀sán oùn òru
Àt' ìràwọ̀ kì yóò sí mọ́;
Olúwa àwọn ángẹ́lì,
Jẹ́ k' á r' ìmọ́lẹ̀ ayọ̀,
Kí oòkùn pín.
Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́!
Olú ọ̀run
Ọ̀run, ayé ń jubà Rẹ̀
Ọ̀run àt' ayé ń yìn Ọ
Ọ̀gá ọ̀gọ́.