Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 459: Ẹ Máa Tẹ̀ Sí Wájú, Kristẹn Ológun

Onward Christian Soldiers!

Ẹ máa tẹ̀ sí wájú,
Kristẹn ológun,
Máa tejúmọ Jésù,
T' Ó ń bẹ ní 'wájú;
Krístì Olúwa wa
Ni Balógun wa,
Wòó! àsíá Rẹ̀ wà
Ní 'wájú ogun.

Ẹ máa tẹ̀ síwájú,
Kristẹn ológun
Ṣáà tejú mọ́ Jésù,
T' ó ń bẹ níwájú.

Ní orúkọ Jésù,
Ogun Èṣù sá,
Ǹjẹ́ Kristẹn ológun,
Máa ń sọ sí 'ṣẹ́gun
Ọ̀run apáàdì mì,
Ní híhó ìyìn,
Ara gb' ohùn yín ga,
Gb' orin 'yìn s' òkè.

Ẹ máa tẹ̀ síwájú,
Kristẹn ológun
Ṣáà tejú mọ́ Jésù,
T' ó ń bẹ níwájú.

Bí ẹgbẹ́ ogun ńlá,
N' ìjọ Ọlọ́run,
Ara a ń rìn l' ọ̀nà
T' àwọn mímọ́ ń rìn;
A kò yà wá n' ipa,
Ẹgbẹ́ kan ni wa;
Ọkan n' ìrètí l' ẹ̀kọ́,
Ọkan ni ìfẹ́.

Ẹ máa tẹ̀ síwájú,
Kristẹn ológun
Ṣáà tejú mọ́ Jésù,
T' ó ń bẹ níwájú.

Ìtẹ́ àt' ìjọba,
Wọ̀nyí lè parun,
Ṣùgbọ́n ìjọ Jésù
Yóò wà títí láé;
Ọ̀run apáàdì kò
Lè bor' ìjọ yìí;
A ní ìlérí Krístì,
Èyí kò lè yẹ

Ẹ máa tẹ̀ síwájú,
Kristẹn ológun
Ṣáà tejú mọ́ Jésù,
T' ó ń bẹ níwájú.

Ẹ máa bá ni ká lọ
Ẹ̀yin ènìyàn
D' ohùn yín pọ̀ mọ́ wa
L' orin ìṣẹ́gun
Ògo, ìyìn, ọlá,
Fún Krístì Ọba;
Èyí ni yóò máa jẹ́
Orin wa títí.

Ẹ máa tẹ̀ síwájú,
Kristẹn ológun
Ṣáà tejú mọ́ Jésù,
T' ó ń bẹ níwájú.