Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 458: F' Agbára Jà Ìjà Rere

Fight The Good Fight

F' agbára jà ìjà rere
Kríst' ni 'gbàlà oun ẹ̀tọ́ rẹ
F' ọwọ́ lé ìyè, yóò sì jẹ́
Ayọ̀ oun adé rẹ títí.

F' oore-ọ̀fẹ́ jà 'jà rere,
Gb' ojú s' òkè, sì w' ojú Rẹ̀
Ọ̀nà 'yè ṣí sílẹ̀ fún ọ,
Kríst l' ọ̀nà, Òun sì l' ère.

Kọ àníyàn rẹ s' àpákan,
Sìmí lé E, Òun yóò sì pèsè;
Ìgbékẹ̀lé rẹ yóò fi hàn
Pé Kríst' ni ìyè àt' ìfẹ́ rẹ

Má bẹ̀rù, má sì ṣe sààrè
Kì í yípadà, wò, sì ṣ' ọ̀wọ́n;
Ṣàá gbàgbọ́, 'wọ yóò sì rí i pé
Krístì l' ohun gbogbo fún ọ.