Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 456: Jí Ọkàn Mi
Awake My Soul
Jí ọkàn mi, dìde gírí,
Máa lépà ń sọ kíkán;
F' ìtara súre ìje yìí
Fún adé tí kì í sà.
Ọlọ́run ń f' ohùn ìtara
Kè sí ọ lát' òkè;
Tìka Rẹ̀ l' Ó ń pín ère náà,
T' o ó ń nàgà láti wọ.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹlẹ́rì wà,
Tí wọ́n ń f' ojú sùn ọ́
Gbàgbé ìrìn àtẹ̀hìnwá,
Ṣàá máa tẹ̀ síwájú.
Olùgbàlà, 'Wọ l' ó mú wa
Bẹ̀rẹ̀ ìje wa yìí;
Nígbàt' a bá dé wa l' adé,
A ó wọlé l' ẹsẹ̀ Rẹ̀.