Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 455: Ìjà Ńlá Ìkẹ̀hìn Náà Dé

The Last Great Conflict Now Is On

Ìjà ńlá ìkẹ̀hìn náà dé,
Ọpágun ń fẹ́ lélé
Immanuel Ọm' Aládé
Ń fún ohùn ìpè náà
Àfẹ́ ayé fẹ́rẹ̀ pín ná,
A gbọ́ 'kẹ́rọ̀rà rẹ̀;
Tani yóò jíyìn rere náà?
Tani yóò j' ayọ̀dà?

A gbọ́ ìpè Balógun wa,
A ó bá a lọ s' ogun
A ó sìn Immanuel wa
Tít' ibi yóò fi tán
Olúwa má ṣe jẹ́ k' ìdà
Tàbí ọ̀rọ̀ wéré
Mú wa dúró tàbí y' ẹsẹ̀
Tít' ìpadàbọ̀ Kríst'.

"Ìfẹ́ Krístì ni ó ń rọ wa"
A f' ohun gbogbo fún-Un
Láti ṣiṣẹ́ níbikíbi
Tí Olúwa bá yàn
Kí ìran yìí tó rékọjá,
Ilẹ̀ okun, yóò gbọ́
Iṣẹ́ ta a ràn sí gbogb' ayé
Pé Ọba náà dé tán.