Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 454: Ìpè Fún Ọmọ Ogun

A Call For Loyal Soldiers

Ìpè fún ọmọ ogun
Ń tọ gbogbo wa wá;
Ọmọ ogun fún 'jà,
'Wọ yóò jẹ 'pè náà?
'Wọ́ yóò tètè dáhùn?
Pẹ̀l' ọkàn ayọ̀?
'Wọ yóò f' oókọ sílẹ̀
B' ọmọ ogun bí.

Ọmọ ogun fún Jésù,
Olóòt' ọmọ;
Àwọn mí-ì f' oókọ 'lẹ̀,
Ìwọ nkọ́?
Jésù ni Balógun,
A kì yóò bẹ̀rù;
'Wọ yóò f' oókọ sílẹ̀
B' ọmọ ogun bí?

Jésù ń pè ọmọ ogun
T' ó kún f' agbára
Ọm' ogun tí yóò sìn
Ní ojòojúmọ́;
Òun kì yóò kọ ọ́ lé
Òun yóò f' sún mọ́ Ọ;
Wọ́ yóò f' oókọ sílẹ̀
B' ọmọ ogun bí?

Ọmọ ogun fún Jésù,
Olóòt' ọmọ;
Àwọn mí-ì f' oókọ 'lẹ̀,
Ìwọ nkọ́?
Jésù ni Balógun,
A kì yóò bẹ̀rù;
'Wọ yóò f' oókọ sílẹ̀
B' ọmọ ogun bí?

Ó ń pè ọ nítorí pé
Ó fẹ́ ọ púpọ̀
Ẹn' t' ó kú nítorí
Ẹ̀ṣẹ̀ aráyé;
Ó ń pè ọ nísìyìí,
Pẹ̀l' ohùn gòòrò,
'Wọ yóò f' oókọ sílẹ̀
B' ọmọ ogun bí?

Ọmọ ogun fún Jésù,
Olóòt' ọmọ;
Àwọn mí-ì f' oókọ 'lẹ̀,
Ìwọ nkọ́?
Jésù ni Balógun,
A kì yóò bẹ̀rù;
'Wọ yóò f' oókọ sílẹ̀
B' ọmọ ogun bí?

'Gbàt' ogun bá sì parí.
T' a bá sì ṣẹ́gun;
'Gbàt' àwọn olóòtọ́
Bá kó ara jọ,
Òun yóò f' adé ògo
F' àwọn t' ó wà n' bẹ̀;
'Wọ yóò f' oókọ sílẹ̀
B' ọmọ ogun bí?

Ọmọ ogun fún Jésù,
Olóòt' ọmọ;
Àwọn mí-ì f' oókọ 'lẹ̀,
Ìwọ nkọ́?
Jésù ni Balógun,
A kì yóò bẹ̀rù;
'Wọ yóò f' oókọ sílẹ̀
B' ọmọ ogun bí?