Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 452: Dìde Ọm' Ogun Kríst'
Soldiers Of Christ Arise
Dìde, ọm' ogun Kríst'
Ẹ gbé 'hàmọ́rà wọ
L' agbára t' Ọlọ́run fún yín
Nípasẹ̀ Ọmọ Rẹ̀;
Olúwa Ọm' ogun
Lè fún ni l' agbára
Ẹni bá a gbékẹ̀lé Jésù,
Ó jù aṣẹ́gun lọ.
Ẹ dúró n' torí náà,
Nínú agbára Rẹ̀
Ẹ f' ìhàmọ́rà Ọlọ́run
D' àmúrè fún 'jà náà
Máa ṣọ́ra n' gbà gbogbo
Mú 'hàmọ́rà yín dán
Ẹ máa tẹ̀lé Balógun yín,
Ẹ sì máa gbàdúrà.
Ẹ máa tẹ̀ síwájú,
Ẹ jà, ẹ gbàdúrà;
Ẹ tẹ̀ agbára oòkùn bà,
K' ẹ e sì ṣe ogun náà;
Gbàt' ìjà bá parí
Tẹ ẹ ṣ' ohun gbogbo tán
Nú Kríst' nìkan l' ẹ lè ṣẹ́gun
Kẹ e sì dúró gbọn-in gbọn-in.