Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 449: Kristẹni, Má Tìí Wá 'Simi

Christians Seek Not Yet Repose

Kristẹn, Má tìí wá 'simi,
Máṣe l' èrò ìrora;
Ní àárín ọ̀tá l' ó wà;
"Máa ṣọ́ra!"

Wọ 'hàmọ́rà-ọ̀run rẹ,
Wọ ó l' ọ̀sán àti l' òru;
Èṣù bá, ó ń dódè rẹ;
"Máa ṣọ́ra!"

Gb' ohùn àwọn aṣẹ́gun,
Wọ́n mọ ọ̀nà ajagun,
Gbogbo wọn ń wí l' ohùn kan;
"Máa ṣọ́ra!"

Gbọ́ ohùn Olùgbàlà,
Ẹni tí ó fẹ́ tẹ̀lé E;
P' ọ̀rọ̀ Rẹ mọ́ s' àyà rẹ;
"Máa ṣọ́ra!"

Máa ṣọ́ra, bí ẹni pé
Níbẹ̀ ni 'ṣẹ́gun rẹ wà;
Gbàdúrà fún 'ránlọ́wọ́;
"Máa ṣọ́ra!"