Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 447: Gbọ́ Ohùn Àlòrè, Jí Ara, Jí

Hark 'Tis The Watchman's Cry

Gbọ́ ohùn àlòrè, Jí ara, jí
Jésù má féré dé, Jí ara jí:
Ọmọ òru ni í sùn,
Ọmọ ìmọ́lẹ̀ l' ẹyin,
Tiyín l' ògó dídàn jí, ara, jí.

Sọ f' ẹgbẹ́ t' ó ti jí,
Ara ṣọ́ra;
Àṣẹ Jésù dájú, Ara, ṣọ́ra;
N' ìlẹ̀kùn Olúwa yín,
Bí Ó tilẹ̀ pẹ́ dé, Ara ṣọ́ra.

Gbọ́ ohùn ìríjú
Ara, ṣiṣẹ́;
Iṣẹ́ náà kárí wa,
Ara, ṣiṣẹ́; Ọgbà Olúwa wa,
Kún fún 'ṣẹ́ nígbà gbogbo;
Òun yóò fún yín l' ère;
Ara ṣiṣẹ́

Gb' ohùn Olúwa wa.
Ẹ gbàdúrà Bẹ́ ẹ fẹ́ k' inú Rẹ dùn
Ẹ gbàdúrà; Ẹ̀ṣẹ̀ mú 'bẹ̀rù wá,
Àìlera ń f' olùrànwọ́
Ní ìjàkadì yín
Ẹ gbàdúrà.

Kọ orin ìkẹ̀yìn,
Yìn, ara, yìn;
Mímọ́ ni Olúwa.
Yìn ara, yìn; Kìl' ó tún yẹ ahọ́n,
T' ó féré b' áńgẹ́lì kọrin,
T' ọ̀run yóò kọ títí,
Yìn ara, yìn.