Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 445: Ọmọ Ìjọba

Heir Of The Kingdom

Ọmọ ìjọba, èéṣe tí 'wọ fi ń sùn?
Èéṣe tí 'wọ fi ń sùn nítòsí 'lé?
Jí dìde, kí o sì dì àmùrè rẹ,
Ṣe kánkán, tọ́r' àkókò tẹ́tẹ́ ń lọ.

Ọmọ ìjọba, èéṣe tí 'wọ ń lọ́ra
'Gbà tí 'wọ lè eré lọkèèrè?
Dìde, sì múra, 'tọ́r' Olùgbàlà ń bọ̀;
Ṣe gírí, sì kí kàábọ̀, b' ó ti ń bọ̀.

Àwọn orílẹ̀-èdè nlá kún f' ẹ̀rù
Àt' ìfọ̀yà nínú 'jà àt' ọ̀tẹ̀;
Gbogbo wọ̀nyìí j' àmì bíbọ̀ Olúwa.
Ọmọ ìjọba máṣe jáfárà.

Máṣe gbé ara lé ohun ayé yìí,
Wò bí ògó rẹ̀ ti ṣe ń kojá lọ;
Tú okùn ìdè tí ọ̀tá fi dè ọ,
Ọmọ ìjọba kúrò nínú rẹ̀.

F' ojú s' ọ̀nà kan, kó o sì gb' orí sókè,
Rètí bíbọ̀ ògó ọba ayé;
Wò bí ìmọ́lẹ̀ ti ń tàn lí òkè,
Ọmọ ìjọba yọ̀, kó o sì kọrin.