Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 444: Ìgbọ́ràn Sáà Sàn Jù Ẹbọ Lọ

Obedience Is Far Better Than Sacrifice

Ìgbọ́ràn sáà sàn jù ẹbọ lọ,
L' Olúwa wí;
Ìfẹ̀tísílẹ̀ sì sàn jù
Ọ̀rá àgbò lọ.

Yí s' Olúwa, yóò sì ṣàánú fún ọ,
Pa gbogbo àwọn òfin Rẹ mọ́,
Ìgbọ́ràn sáà sàn jù ẹbọ lọ
L' Olúwa wí,
Ìfẹ̀tísílẹ̀ sì sàn jù ọ̀rá àgbò lọ.

Ẹyin t' ó wí pé, kò sí òfin,
Krístì ti kú
Ẹ rántí àṣẹ Rẹ n' nú ìwé
Tí ó fún ni.

Yí s' Olúwa, yóò sì ṣàánú fún ọ,
Pa gbogbo àwọn òfin Rẹ mọ́,
Ìgbọ́ràn sáà sàn jù ẹbọ lọ
L' Olúwa wí,
Ìfẹ̀tísílẹ̀ sì sàn jù ọ̀rá àgbò lọ.

Rántí p' olùṣe ọ̀rọ̀ náà
Nìkan la à búkún;
Gbígbọ́ kò tó, ṣùgbọ́n ṣíṣe
Lo ní ìbùkún.

Yí s' Olúwa, yóò sì ṣàánú fún ọ,
Pa gbogbo àwọn òfin Rẹ mọ́,
Ìgbọ́ràn sáà sàn jù ẹbọ lọ
L' Olúwa wí,
Ìfẹ̀tísílẹ̀ sì sàn jù ọ̀rá àgbò lọ.