Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 443: Gbàt' A Ń Bá Jésù Rìn
When We Walk With The Lord
Gbàt' a ń bá Jésù rìn,
N' nú mọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ,
Wò ògó t' ó tàn sí ọ̀nà wa!
Gbàt' a bá ń ṣe 'fẹ́ Rẹ,
Òun yóò wà pẹ̀lú wa,
Àt' àwọn t' ó bá tún gbẹ́kẹ̀lé E.
Sáà gbẹ́kẹ̀lé E,
Ọ̀nà míràn kò sí
Láti l' ayọ̀ n' nú Jésù
Ìwọ sáà gbẹ́kẹ̀lé E.
Ibi kan kò lè ṣe,
Kò lè sí 'bànújẹ́,
Tí ẹ̀rín Rẹ kò lè mú kúrò;
Kò sí omijé kan,
Kò sí sì ẹ̀rù kan
T' ó lè wà gbàt' a bá gbẹ́kẹ̀lé E.
Sáà gbẹ́kẹ̀lé E,
Ọ̀nà míràn kò sí
Láti l'ayọ̀ n' nú Jésù
Ìwọ sáà gbẹ́kẹ̀lé E.
Kò sí ìnira kan
Tàb' ẹ̀dùn tí a ní,
Ṣùgbọ́n Ó san ẹ̀san iṣẹ́ wa;
Kò s' ẹ̀dùn tàb' òfo,
Kò sí s' àgbélébùú
T' a kò bùkún bá a bá gbẹ́kẹ̀lé E.
Sáà gbẹ́kẹ̀lé E,
Ọ̀nà míràn kò sí
Láti l'ayọ̀ n' nú Jésù
Ìwọ sáà gbẹ́kẹ̀lé E.
Ṣùgbọ́n a kò léè mọ̀
Ayọ̀ ìfẹ́ Tirẹ
Títí a ó fi f' ara wa fún-Un;
N' tọ́r' ojúrere Rẹ
Àt' ayọ̀ t' Ó ń fún ni,
Wá fún àwọn tí yóò gbẹ́kẹ̀lé E.
Sáà gbẹ́kẹ̀lé E,
Ọ̀nà míràn kò sí
Láti l'ayọ̀ n' nú Jésù
Ìwọ sáà gbẹ́kẹ̀lé E
Ní ìdàpọ̀ dídùn
L' a ó wà l' ẹsẹ̀ Rẹ
A ó rìn pẹ̀lú Rẹ ní ọ̀nà,
A ó ṣe ohun t' Ó wí,
A ó lọ bí t' Ó fẹ́,
Má bẹ̀rù, Ìwọ sáà gbẹ́kẹ̀lé E.
Sáà gbẹ́kẹ̀lé E,
Ọ̀nà míràn kò sí
Láti l'ayọ̀ n' nú Jésù
Ìwọ sáà gbẹ́kẹ̀lé E.