Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 442: Ilé Ayọ̀ Àt' Ìfẹ́ Ni Ilé T' Ọlọ́run Wà
Happy The Home When God Is There
Ilé ayọ̀ àt' ìfẹ́ ni
Ilé t' Ọlọ́run wà;
Gbà 'fẹ́ àt' àdúà wọn j' ọ̀kan
Láti simi l' ọ̀run.
Ilé ayọ̀ ni ilé náà
Ní 'bi Jésù jọba
N' b' àwọn ọmọ ń fọ̀n rere Rẹ̀
T' àwọn òbí ń gbé E ga.
Ilé ayọ̀ ni 'lé t' àdúà,
Àti ìyìn ń jọba;
T' àwọn òbí fẹ́ wẹ̀ Mímọ́,
Àt' ẹwà inú rẹ̀
Olúwa jẹ́ k' a p' ẹnu pọ̀
L' àdúà f' àlááfíà;
K' ọkàn wa j' ọ̀kan n' nú 'fẹ́ Rẹ,
Kí 'fẹ́ lè gb' ọkàn wa.