Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 441: Nínú Krístì Kò Sí Ẹyà

In Christ There Is No East Or West

Nínú Krístì kò sí ẹyà,
'Nú Rẹ kò sí 'yàpà;
Ṣùgbọ́n okùn 'fẹ́ kan ṣoṣo
Ni gbogbo àgbáyé.

Nínú Rẹ ni gbogbo ọkàn
Lè b' Ẹlẹ́dàá sọ̀rọ̀;
Iṣẹ́ Rẹ jẹ́ okùn wúrà
T' ó so gbogb' ẹ̀dá pọ̀.

Ẹ jumọ̀ dìde n' nú ìgbàgbọ́
Ẹyà ó wù tẹ́ ẹ lè jẹ́;
Ẹni ń sìn Bàbá b' ọmọ Rẹ̀,
Òun náà ni 'yẹ̀kan mi.

Nínú Krístì ẹ parapọ̀,
Ni gbogb' orílẹ̀ èdè;
Gbogbo ọkàn t' ó gbà Jésù
Yóò j' ọ̀kan l' àgbáyé.