Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 439: Fi N' Agbára Rẹ F' Olúwa
Give Of Your Best To The Master
Fi n' agbára rẹ f' Olúwa,
Fún-Un n' agbára èwẹ rẹ
Fi gbogbo ọkàn gbígbóná
Jà ogun fún òtítọ́;
Jésù fi àpẹẹrẹ lé 'lẹ̀,
Akíni àt' ògboyà ni;
F' ọkàn ìsìn òótọ́ rẹ fún-Un
F' èyí t' ó dára jù fún-Un.
Fi n' agbára rẹ f' Olúwa,
Fún-Un n' agbára èwẹ rẹ,
Gbé 'hàmọ́rà ìgbàlà wọ̀,
Jà ogun fún òtítọ́.
Fi n' agbára rẹ f' Olúwa
Fi l lékè ọkàn rẹ,
Fi ṣe 'bí kìíní n' ìsìn rẹ,
Yà ara rẹ sí Mímọ́;
Fi sílẹ̀, a ó sì tì fún ọ,
Bàbá f' Ọmọ Rẹ̀ fún wa;
Fi pẹ̀lú ọkàn ọpẹ́ sìn ín,
F' èyí t' ó dára jù fún-Un
Fi n' agbára rẹ f' Olúwa,
Fún-Un n' agbára èwẹ rẹ,
Gbé 'hàmọ́rà ìgbàlà wọ̀,
Jà ogun fún òtítọ́.
Fi n' agbára rẹ f' Olúwa,
'Tórí pé ó fẹ́ràn rẹ;
Ó f' ẹ̀mí Rẹ̀ rà ọ padà,
Ó bò ògó Rẹ̀ sílẹ̀;
Ó f' ẹ̀mí Rẹ̀ lé 'lẹ̀ jẹ́jẹ́
Láti gbà ọ lọ́w' ẹ̀ṣẹ̀;
Fi ìyìn àtọkàn wá fún-Un,
F' èyí t' ó dára jù fún-Un.
Fi n' agbára rẹ f' Olúwa,
Fún-Un n' agbára èwẹ rẹ,
Gbé 'hàmọ́rà ìgbàlà wọ̀,
Jà ogun fún òtítọ́.