Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 438: Olúwa Èmi Fẹ́ N' Ìpín
Sharing In The Joys Of Service
Olúwa èmi fẹ́ n' ìpín
Nínú iṣẹ́ Rẹ;
T' ayọ̀ t' ayọ̀ ni n ó fi fi
Ọkàn mi fún Ọ.
Jésù gbà mí pátápátá,
Gbà gbogb' ọkàn mi,
Jẹ́ kí 'fẹ́ Rẹ kọ́ mi bí n ó
Ti rìn súnmọ́ Ọ.
Àwọn áńgẹ́lì l' ọ̀run ń fi,
Ayọ̀ ṣe 'fẹ́ Rẹ;
Èmi náà yóò fi gbogb' ọkàn
Mi rìn súnmọ́ Ọ
Jésù gbà mí pátápátá,
Gbà gbogb' ọkàn mi,
Jẹ́ kí 'fẹ́ Rẹ kọ́ mi bí n ó
Ti rìn súnmọ́ Ọ.
Títí láéláé agbára Rẹ,
L' èm' ó gbẹ́kẹ̀lé,
Títí ìmọ́lẹ̀ ògó Rẹ
Yóò fi yọ lókè.
Jésù gbà mí pátápátá,
Gbà gbogb' ọkàn mi,
Jẹ́ kí 'fẹ́ Rẹ kọ́ mi bí n ó
Ti rìn súnmọ́ Ọ.