Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 437: A Ń Bá Ọ Ṣiṣẹ́ Pọ̀

Working O Christ With Thee

A ń bá Ọ ṣiṣẹ́ pọ̀,
Kríst' Olúwa;
Bí àwa tilẹ̀ jẹ́
Ẹni aìyé;
A f' ara wa fún Ọ,
A wà láàyè fún Ọ,
Nípa oòr' ọ̀fẹ́ Rẹ,
L' àwa ń ṣiṣẹ́.

A ń bá Ọ ṣiṣẹ́ pọ̀,
Níbi gbogbo;
Pẹ̀lú 'tara l' a ń fẹ́
Rí bó O ti rí;
A ń m' aláìní wọ 'lé,
Aṣákò k' rọ̀ n' ẹsẹ̀;
Láti gbà ọkàn là,
L' àwa ń ṣiṣẹ́.

Kò rẹ̀ wá láti bá
Krístì ṣiṣẹ́;
'Ṣe wa kò lè tó
Èyí tó O ṣe,
Ayọ̀ wa l' èyí pé
"Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ tó"
'Gbàt' a ń bá Ọ ṣiṣẹ́
Àwa l' ayọ̀.

'Tórí náà, jẹ́ k' á lè
Bá Ọ ṣiṣẹ́;
Tít' a ó fi gb' ayé là
Kúrò n' ẹ̀ṣẹ̀;
Títí gbogb' ènìyàn
Yóò máa yìn Ọ l' ògó;
T' àwọn pẹ̀lú wa yóò,
Bá Ọ ṣiṣẹ́.