Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 436: Nínú Ọkàn Jésù

In The Heart Of Jesus

Nínú ọkàn Jésù,
Ìfẹ́ wà fún ọ,
Ìfẹ́ mímọ́, tùtù,
'Fẹ́ jíjìn tòótọ́.
Yóò ṣe kú 'wọ nìkan
T' ó ń ronú ore,
'Gbà tí ọkàn Jésù
Kún fún 'fẹ́ òótọ́.

Nínú àyà Jésù
Èrò wà fún ọ,
Èrò àlááfíà
Àt' ìgbàlà rẹ.
Èéṣe tí o ò fọ̀yà
T' ọkàn rẹ dààmú
'Gbà tí ọkàn Jésù
Ń kè àwọn t' Ó rà.

Nínú ọgbà Jésù,
Àáyè wà fún ọ,
Iṣẹ́ t' áńgẹ́lì pàápàá
Yóò yọ̀ láti ṣe
Èéṣe t' ó fi ń dúró
Dè 'ṣe nlá t' ayé,
Gbàt' àáyè wà fún ọ
Níbi 'ṣẹ́ Jésù.

Nínú ilé Jésù
Àáyè wà fún ọ,
Ilé ayọ̀ dídán
T' ó tùtù níní.
Ẹ̀ẹ̀ṣiṣẹ́ tí o ó fi
Máa rìn b' aṣákò
Gbàt' àáyè wà fún ọ
N' nú ilé Jésù.