Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 435: Ṣe Ìfẹ́ Tirẹ, Ṣe Ìfẹ́ Rẹ

Have Thine Own Way Lord

Ṣe ìfẹ́ Tirẹ, Ṣe ìfẹ́ Rẹ,
Wọ l' Amọ̀kòkò amọ̀ ni mí,
Mọ mí, sì dá mi, bí ìfẹ́ Rẹ.
Mo dúró dè Ọ ní 'dákẹ̀jẹ́.

Ṣe ìfẹ́ Tirẹ, ṣe ìfẹ́ Rẹ!
Wádìí ọkàn mi, kó O dán mi wò!
Wẹ̀ mí Olúwa, kí n funfun láú,
Bí mo ti ń f' ìrẹ̀lẹ̀ tẹríba.

Ṣe ìfẹ́ Tirẹ, ṣe ìfẹ́ Rẹ!
Mo jẹ́ aláàrẹ̀, ràn mí lọ́wọ́!
Gbogbo agbára l' ó jẹ́ Tirẹ!
Wò mí sàn, Olùgbàlà Mímọ́!

Ṣe ìfẹ́ Tirẹ, ṣe ìfẹ́ Rẹ!
Jọba lórí mi, t' ọkàn, t' ara!
F' Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ kún mi tó bẹ́ẹ̀
T' ayé yóò fi rí Krístì n' nú mi.