Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 433: Yìn Ọlọ́run, Yìn ín Láéláé

Praise To God, Immortal Praise

Yìn Ọlọ́run, yìn ín láéláé,
Fún ìfẹ́ ojòojúmọ́,
Orísun ayọ̀ gbogbo
Kí yìn Rẹ gb' ẹnu wa kan.

Fún ire t' oko ń mú wá:
Fún oúnjẹ t' a ń mú l' ọgbà:
Fún èso igi pẹ̀lú;
Àt' òróró tí a ń lo.

Fún gbogb' ẹran ọ̀sìn wa
T' òun sírí ọkà gbogbo;
Ọ̀run tí ń ṣe 'rì sílẹ̀;
Oòrùn tí ń m' oòrù rẹ̀ wá.

Gbogbo ǹkan t' ẹ̀ẹ̀rùn ń mú wá
Kákìrí gbogbo ilẹ̀;
Àt' èso ìgbà òjò
Lát' inú ẹkùn rẹ̀ wá

'Wọ elébùn gbogbo wọn
Orísun ìbùkún wa;
'Tórí náà ọkàn wa yóò
F' ìyìn àt' ọpẹ́ fún Ọ.