Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 432: Olúwa 'Kórè, 'Wọ L' A Ń Yìn
Lord Of The Harvest, Thee We Hail
Olúwa 'kórè, 'Wọ l' a ń yìn;
Ìlérí Rẹ 'gbàá ni kò yẹ;
Oríṣi ìgbà sì ń yípo
Ọdọọdún kún fún oore Rẹ,
Lójọ́ òní, àwa dupẹ́;
Jẹ́ k' ìyìn gbà ọkàn wa kan.
B' àkókò 'rúgbìn mú wa yọ̀;
B' ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ń mú oòrù wá;
'Gbàt' omi òjò bá ń rìn 'lẹ̀;
Tàb' ìgbàt' ìkórè báà pọ́n,
'Wọ Ọba wa l' a ó máa yìn;
Wọ l' alákòóso gbogbo wọn.
Jù gbogbo rẹ̀ lọ, nígbà tí
Ọwọ́ Rẹ fún ọ̀pọ̀ ká 'lẹ̀;
Gbàt' ohùn ayọ̀ gbilẹ̀ kan
B' ẹ̀dá ti ń kó ire wọn jọ;
Àwa pẹ̀lú yóò máa yìn Ọ
Oore Rẹ ni gbogbo wa ń pín.
Olúwa 'kórè, Tirẹ ni
Òjò tí ń rọ̀, oòrùn tí ń rán;
Irúgbìn tí a gbìn tí ń rán;
Tirẹ l' ọgbọ́n tí ń mú u dàgbà;
Ọ̀tún l' ẹ̀bùn Rẹ l' ọdọọdún
Ọ̀tún n' ìyìn Rẹ l' ẹnu wa.