Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 431: Ní Ìgbà Ayọ̀ Ìkórè

In The Glad Time Of The Harvest

Ní ìgbà ayọ̀ ìkórè,
L' ọ̀pìn ayé èṣe yìí,
Ọba náà yóò sì f' ara hàn,
Láti ṣe 'dájọ́ ayé;
Ayé yóò kó 'ṣúra rẹ̀ jọ,
Wọ́n ó wá síwájú 'tẹ́;
Ìgbà náà l' a ó gb' ère wa,
Gb' Ọba bá ń p' àwọn Tirẹ̀.

À, ayọ̀ àwọn ẹ̀ẹ́yàn Rẹ̀!
Wọ́n ti pẹ́ lórí ayé,
T' ọkàn wọn sì ń fà sí ilé,
T' ìfẹ́ wọn pọ̀ s' Ọlọ́run
Wọ́n ó ní ìyè àìlópin,
Wọ́n ó mọ̀ b' a ti mọ wọ́n,
Wọ́n ó kojá 'lẹ̀kùn dídàn,
Gb' Ọba bá ń p' àwọn Tirẹ̀.

Wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ fún 'kórè pẹ́,
Wọ́n f' omijé fún 'rúgbìn;
Wọ́n ó s' ẹrù kalẹ̀ láìpẹ́
Lọ́pìn ayé èṣe yìí;
Wọ́n ó pín nín' ayọ̀ ọ̀run,
Kò tún ní sí ẹ̀dùn mọ́;
Wọ́n ó gb' adé pẹ̀lú 'ràwọ̀,
Gb' Ọba bá ń p' àwọn Tirẹ̀.

Àwa ó k' àwọn àyànfẹ́,
T' ó ti fi wa sílẹ̀ lọ;
Gbogbo 'bànújẹ́ yóò fò lọ
Gbàt' Olùgbàlà bá dé;
Kò ní sí bànújẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
Kò ní sí aníkàngbé,
À, a ń rètí ọj' ayọ̀ náà
Gb' Ọba bá ń p' àwọn Tirẹ̀.