Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 430: A Ń Roko, A Ń Fúnrúgbìn

We Plough The Fields

A ń roko, a ń fúnrúgbìn
Sínú oko gbogbo,
Ṣùgbọ́n ọwọ́ Ọlọ́run
L' ó ń mú 'rúgbìn dàgbà,
Ó ń rán òtútù àt' oòrù
Láti mú èso pọ́n,
Èfúùfù àti oòrùn,
Àt' òjò t' ó ń rìn 'lẹ̀

Láti ọ̀run wá ni
Ẹ̀bùn rere gbogbo;
F' ọpẹ́ f' Olúwa, ẹ s' ọpẹ́
Fún gbogbo ìfẹ́ Rẹ̀.

Òun nìkan li Ẹlẹ́dàá
Ọ̀run àti ayé;
Ó fún ìtànná l' ẹwà;
Ó mú ìràwọ̀ tàn;
Ìjì gbà ohùn Rẹ̀ gbọ́,
Ó ń bọ́ àwọn ẹyẹ;
Pàápàá àwọn ọmọ Rẹ̀
L' ó ń bọ́ lójòojúmọ́.

Láti ọ̀run wá ni
Ẹ̀bùn rere gbogbo;
F' ọpẹ́ f' Olúwa, ẹ s' ọpẹ́
Fún gbogbo ìfẹ́ Rẹ̀.

Bàbá, a f' ọpẹ́ fún Ọ.
F' ohun rere gbogbo,
Fún 'gbà 'rúgbìn òun 'kórè,
F' ẹ̀mí, 'lera, oúnjẹ;
Gbà ẹ̀bùn tí a mú wá
Tó Ọ fún wa 'nú 'fẹ́ Rẹ
Àní ohun t' Ó fẹ́ jù
L' ọpẹ́ àt' ìyìn wa.

Láti ọ̀run wá ni
Ẹ̀bùn rere gbogbo;
F' ọpẹ́ f' Olúwa, ẹ s' ọpẹ́
Fún gbogbo ìfẹ́ Rẹ̀.