Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 429: Wá Ẹyin Olópẹ́ Wá

Come Ye Thankful People

Wá ẹyin olópẹ́ wá,
Gbé orin ìkórè ga;
'Kóorè gbogbo ti wọ 'lé
K' òtútù oyè tóó dé;
Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wa
L' Ó ti pèsè f' àìní wa;
Wá k' a rè 'lé Ọlọ́run
Gbé orin ìkórè ga.

Oko Ọlọ́run l' ayé,
Láti ṣ' èso ìyìn Rẹ̀;
Àlìkàmá àt' ẹ̀pọ̀
Ń dàgbà f' àrò tàb' ayọ̀;
Ẹ̀ẹ́nù ná ìpè tẹ́ lè é,
Sírí ọkà níkẹ̀yìn;
Olúwa 'kórè, mú wa
Jẹ́ èso rere fún Ọ.

N' tórí Ọlọ́run wá ń bọ̀,
Yóò sì kórè Rẹ̀ sí 'lé;
Òun ó gbọ́n gbogbo pàntí
Kúrò l' oko Rẹ̀ n' 'jọ́ náà;
Yóò f' àṣẹ f' àwọn áńgẹ́lì
Láti gbà ẹ̀pọ̀ s' iná,
Láti kó àlìkàmá
Sí àbà Rẹ̀ títí láé.

Bẹ́ẹ̀ ni, Ìjọ t' ó ṣẹ́gun,
Wá, gbé orin 'kórè ga;
A ti kó gbogb' ẹ̀ẹ́ 'yàn jọ
Kúrò l' ẹ̀ṣẹ̀ àt' àrò,
A sọ wọ́n di mímọ́ láé,
Kí wọ́n lè máa bá Ọ gbé;
Wá, t' Ìwọ t' Áńgẹ́lì Rẹ
Gbé orin ìkórè ga.